26 Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa
27 ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
28 Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.
29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.
30 Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,
31 Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn.
32 Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.