12 Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”
13 Olúwa bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.
14 Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésúrónì àti Kámì. Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Rúbẹ́nì.
15 Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì.
16 Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:Gésónì, Kóhábì àti Mérárì: Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17 Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì.
18 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì. Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.