15 Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì.
16 Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:Gésónì, Kóhábì àti Mérárì: Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17 Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì.
18 Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì. Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19 Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Músíhì.Ìwọ̀nyí ni ìran Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
20 Ámírámù sì fẹ́ Jókébédì arákùnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jókébédì sì bí Árónì àti Mósè fún un. Ámírámù lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
21 Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà, Nẹ́fẹ́fì àti Ṣíkírì.