27 Àwọn ni ó bá Fáráò ọba Éjíbítì sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni Éjíbítì, àní Mósè àti Árónì yìí kan náà ni.
28 Nígbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ni Éjíbítì,
29 Ó ni “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Fáráò ọba Éjíbítì.”
30 Ṣùgbọ́n Mósè sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ̀n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Fáráò yóò ṣe fi etí sí mi?”