4 Èmí sì tún fi idi májẹ̀mu mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénánì, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjòjì.
5 Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn tí àwọn ará Éjíbítì mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mu mi.
6 “Sọ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì: ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúró nínú àjàgà àwọn ará Éjíbítì. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúró ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.
7 Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ̀ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúró nínú àjàgà àwọn ará Íjíbítí.
8 Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù. Ísáákì àti Jákọ́bù. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni Olúwa.’ ”
9 Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.
10 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè.