12 Lẹ́yìn tí Mósè àti Árónì tí kúrò ní ìwájú Fáráò, Mósè gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sókè sí Olúwa nípa àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ó ti ran sí Fáráò.
13 Olúwa sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Mósè tí béèrè. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì kú nínú ilé àti ní ìta, gbangba àti nínú oko.
14 Wọ́n sì kó wọn jọ ni okíti okíti gbogbo ilẹ̀ sì ń rùn.
15 Ṣùgbọ́n ni ìgbà tí Fáráò rí pé ìtura dé, ó sé ọkàn rẹ̀ le kò sì fetí sí Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí.
16 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ fún Árónì, ‘Na ọ̀pá rẹ jáde kí ó sì lu eruku ilẹ̀,’ jákè jádò gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì ni erùpẹ̀ ilẹ̀ yóò ti di kòkòrò-kantíkantí.” (Kòkòrò kan tí ó ní ìyẹ́ méjì tí ó sì ń ta ni)
17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí.
18 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn onídán gbìdánwò láti da kòkòrò-kantíkantí pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, wọn kò le è ṣé. Kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ẹranko wọn.