22 “ ‘Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ náà, èmi yóò ya ilẹ̀ Góṣénì sọ́tọ̀, níbi tí àwọn ènìyàn mi ń gbé, ọ̀wọ́ eṣinṣin kankan ki yóò dé ibẹ̀. Kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, èmi ni Olúwa, mo wà ni ilẹ̀ yìí.
23 Èmi yóò pààlà sáàárin àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”
24 Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Fáráò àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.
25 Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”
26 Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá?
27 A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”
28 Nígbà náà ni Fáráò wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú ihà, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”