23 Èmi yóò pààlà sáàárin àwọn ènìyàn mi àti àwọn ènìyàn rẹ. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí yóò ṣẹlẹ̀ ni ọ̀la.’ ”
24 Olúwa sì ṣe èyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣinṣin sì ya wọ ààfin Fáráò àti sí ilé àwọn ìjòyè rẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì bàjẹ́ pẹ̀lú ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ̀n-ọn-nì.
25 Nígbà náà ni Fáráò ránṣẹ́ pe Mósè àti Árónì, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ kí ẹ sì rúbọ sí Ọlọ́run yín ní ilẹ̀ yìí.”
26 Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Èyí ló tọ́, ẹbọ tí a ó rú sí Olúwa Ọlọ́run wa yóò jẹ́ ohun ìríra sí àwọn ará ilẹ̀ Éjíbítì. Bí a bá ṣe ìrúbọ ti yóò jẹ́ ìríra ni ojú wọn ṣé wọn kò ní sọ òkúta lù wá?
27 A gbọdọ̀ lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wa.”
28 Nígbà náà ni Fáráò wí pé, “Èmi yóò jẹ́ ki ẹ lọ rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín nínú ihà, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rìn jìnnà jù. Ẹ gbàdúrà fún mi.”
29 Mósè dáhùn ó wí pé, “Bí èmi bá ti kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa, awọn esinsin yóò fi Fáráò, àwọn ìjòyè rẹ, àti àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ ní ọ̀la ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ìdánílójú wa pé Fáráò kò tún ni lo ẹ̀tàn láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn kí ó lọ rú ẹbọ sí Olúwa.”