8 Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì, Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn arákùnrin yóòkù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jérúsálẹ́mù) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Léfì tí ó tó ọmọ ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa.