8 Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jérúsálẹ́mù sí Aritaṣéṣéṣì ọba báyìí:
9 Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó kù—àwọn adájọ́ àti àwọn ìjòyè lórí àwọn ènìyàn láti Tírípólísì, Pásíà, Érékì àti Bábílónì, àwọn ará Élámì ti Súsà,
10 pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Áṣúríbánípálì lé jáde tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samáríà àti níbòmíràn ní agbègbè e Yúfúrátè.
11 (Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.)Sí ọba Aritaṣéṣéṣì,Lati ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Yúfúrátè:
12 Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.
13 Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.
14 Nísinsìn yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba,