1 Nígbà náà wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, láti ìrán Ìdó, sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn.
2 Nígbà náà Ṣerubábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà ọmọ Jóṣádákì gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 Ní àkókò náà Táténáì, Baálẹ̀ ti agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹgbẹ́gbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹ́ḿpìlì yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?”
4 Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”