Ẹ́sírà 5:11-17 BMY

11 Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹ́ḿpìlì ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.

12 Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinésárì ti Kálídéà, ọba Bábílónì lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Bábílónì.

13 Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Ṣáírúsì ọba Bábílónì, ọba Ṣáírúsì pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.

14 Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lọ bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn-án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù. Kí wọn sì mú wá sí tẹ́ḿpílì ní BábílónìNígbà náà ọba Sáírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣesibásárì, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i Baálẹ̀,

15 ó sì sọ fún un pé, “Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, pẹ̀lú kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.”

16 Nígbà náà ni Ṣesibásásárì náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jérúsálẹ́mù lẹ́lẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsínsìn yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.

17 Nísinsìn yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Bábílónì láti rí bí ọba Ṣáírúsì fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.