2 Nígbà náà Ṣerubábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà ọmọ Jóṣádákì gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 Ní àkókò náà Táténáì, Baálẹ̀ ti agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹgbẹ́gbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹ́ḿpìlì yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?”
4 Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”
5 Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbààgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró tí tí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dáríúsì kí wọ́n sì gba èsì tí à kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tétanáì, olórí agbégbé Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbégbé Yúfúrátè, fi ránṣẹ́ sí ọba Dáríúsì.
7 Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:Sí ọba Dáríúsì:Àlàáfíà fún un yín.
8 Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.