4 Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”
5 Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbààgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró tí tí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dáríúsì kí wọ́n sì gba èsì tí à kọ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tétanáì, olórí agbégbé Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbégbé Yúfúrátè, fi ránṣẹ́ sí ọba Dáríúsì.
7 Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé:Sí ọba Dáríúsì:Àlàáfíà fún un yín.
8 Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Júdà, sí tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alágbára. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsinmi, ó sì ń ní ìtẹ̀ṣíwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.
9 A bi àwọn àgbààgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”
10 A sì tún bèèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn silẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.