1 Nígbà náà ni ọba Dáríúsì pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Bábílónì.
2 A rí ìwé kíká kan ní Ékíbátanà ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódí agbégbé Médíà, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀:Ìwé ìrántí:
3 Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Ṣáírúsì, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù:Jẹ́ kí a tún tẹ́ḿpìlì ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní gíga àti àádọ́rùn-ún (90) ẹsẹ̀ bàtà ní fífẹ̀,
4 pẹ̀lú ìpele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ìpele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.
5 Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì kó láti ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù tí ó sì kó lọ sí Bábílónì, di dídá padà sí àyè wọn nínú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.
6 Nítorí náà, kí ìwọ, Táténíà Baálẹ̀ agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà, kúrò níbẹ̀.