Ẹ́sírà 6:10-16 BMY

10 Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀:

11 Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a si fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.

12 Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú.Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà.

13 Nígbà náà, nítorí àṣẹ tí ọba Dáríúsì pa, Táténáì, Baálẹ̀ ti agbégbé Yúfúrátè, àti Ṣétarì-Bóṣénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn pa á mọ́ láì yí ọ̀kan padà.

14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà Júù tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, ìran Ídò. Wọ́n parí kíkọ́ ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti àwọn àṣẹ Ṣáírúsì, Dáríúsì àti Aritaṣéṣéṣì àwọn ọba Páṣíà pọ̀.

15 A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ádárì (oṣù kejì) ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dáríúsì.

16 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—àwọn ìkógun, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.