17 Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ (ọkà), àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ ní Jérúsálẹ́mù.
18 Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tó kù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín.
19 Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jérúsálẹ́mù fún ìsìn nínú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ.
20 Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.
21 Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín
22 tó ọgọ́run kan talẹ́ntì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n jéró, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù wáìnì, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù òróró olífì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.
23 Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbégbé ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀?