Ẹ́sírà 7:20-26 BMY

20 Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.

21 Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín

22 tó ọgọ́run kan talẹ́ntì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n jéró, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù wáìnì, ọgọ́rùn-ún gálọ́ọ̀nù òróró olífì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.

23 Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbégbé ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀?

24 Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sisán owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.

25 Ìwọ Ẹ́sírà, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè—Yúfúrátè—gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà.

26 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.