15 Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀.
16 Nígbà náà ni mo pe Élíásérì, Áríélì, Ṣemanáyà, Elinátanì, Járíbù, Elinátánì, Nátanì, Ṣakaráyà, àti Mésúlámù, ti wọ̀n jẹ̀ olórí, àti Jóíáríbù àti Elinátanì ti wọ̀n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,
17 mo rán wọn sí Ídò, tí ó wà ní ibi ti a ń pè ni Kásífíà, mo sì sọ ohun ti wọn yóò sọ fun Ídò àti àwọn arakunrin rẹ̀ ti wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì ní Kásífíà fún wọn, pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá fún wa fún ilé Ọlọ́run wa.
18 Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣérébáyà wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ìran Máhílì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Ṣérébáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìlélógún (18).
19 Àti Ásábáyà, pẹ̀lú Jésáíyà láti ìran Mérárì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún (20) ọkùnrin.
20 Wọ́n sì tún mú ọ̀kànlénígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì wá-àwọn ènìyàn tí Dáfídì àti àwọn ìjòyè rẹ gbé kalẹ̀ láti ràn àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.
21 Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Áháfà, mo kéde ààwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa.