Ẹ́sírà 8:28-34 BMY

28 Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohum èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Sílífà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.

29 Tọ́jú wọn dáradára títí ìwọ yóò se fi òṣùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jérúsálẹ́mù ní iwájú àwọn aṣáájú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Ísírẹ́lì.”

30 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ ti a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jérúsálẹ́mù.

31 Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Áháfà láti lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa.

32 Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nibi ti a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.

33 Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Mérémótì ọmọ Úráyà lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Élíásérì ọmọ Fínéhásì wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì Jósábádì ọmọ Jésíúà àti Núádáyà ọmọ Bínúì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

34 Gbogbo nǹkan ni a kà tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìgbà náà.