1 Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá wọ́n sì wí pé, Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ti ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ọmọ Kénánì, Hítì, Pérísì, Jébúsì, Ámónì, Móábù Éjíbítì àti Ámórì.
2 Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tó kù yọ nínú hihu ìwà “Àìsòótọ́.”
3 Nígbà tí mo gbọ́ èyí, mo fa àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi ya, mo ja irun orí àti irungbọ̀n mi, mo sì jókòó ní ìbànújẹ́.
4 Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìsòótọ́ àwọn ìgbékùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìbànújẹ́ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀.
5 Ní ìgbà tí o di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀, mo dìde kúrò nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn mi, pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti agbádá mi yíya ní ọrùn mi, mo kúnlẹ̀ lórí eékún mi méjèèjì, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi méjèèjì sí Olúwa Ọlọ́run mi.
6 Mo sì gbàdúrà:Ọlọ́run mi, ojú tì mí gidigidi kò sì yá mi lórí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, Ọlọ́run mi, nítorí ẹṣẹ̀ wá ga ju orí wa lọ, àwọn àìṣedéédéé wa sì ga kan àwọn ọ̀run.
7 Láti ìgbà àwọn baba wá, títí di ìsinsin yìí, àìṣedéédéé wa ti pọ̀ jọjọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà àti ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀ṣín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.