6 Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ọ rẹ̀ pé, “Kí ni kí a ṣe fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti bu ọlá fún?”Nísinsìnyìí Hámánì sì ro èyí fúnra rẹ̀ pé, “Taa ni ó wà níbẹ̀ tí ọba fẹ́ dá lọ́lá ju èmi lọ?”
7 Nítorí náà ó dá ọba lóhùn pé, “Fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá,
8 jẹ́ kí wọn kí ó mú aṣọ ọba èyí tí ọba ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba má a ń gùn, pẹ̀lú ọ̀kan lára adé ọba kí a fi dé e ní orí.
9 Jẹ́ kí a fí aṣọ àti ẹṣin lé ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ lọ́wọ́, kí wọn wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá, kí wọn sì sìn-ín gun ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, kí wọn má a kéde níwájúu rẹ̀ pé, ‘Èyí ni a ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!’ ”
10 Ọba pàṣẹ fún Hámánì pé, “Lọ lẹ́ṣẹ̀ kan náà. Mú aṣọ náà àti ẹṣin kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ fún Módékáì araa Júù, ẹni tí ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba. Má ṣe fi ohunkóhun sílẹ̀ nínú ohun tí o ti yàn.”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Hámánì ṣe mú aṣọ àti ẹṣin náà. Ó fi wọ Módékáì, Módékáì sì wà lórí ẹṣin jákèjádò gbogbo ìgboro ìlú, ó sì ń kéde níwájúu rẹ̀ pé, “Èyí ni a ó ṣe fún ọkùnrin náà ẹni tí inú ọba dùn sí láti dá lọ́lá!”
12 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Módékáì padà sí ẹnu ọ̀nà ọba. Ṣùgbọ́n Hámánì ṣáré lọ ilé, ó sì bo oríi rẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́,