1 Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Sérísésì, tí ó jọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti Índíà títí ó fi dé Etiópíà. (Kúsì)
2 Ní àkókò ìgbà náà ọba Ṣérísésì ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà,
3 Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí olóógun láti Páṣíà àti Médíà, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
4 Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọlá ńlá a rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.
5 Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba se àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Súsà.
6 Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elésé àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mábù. Àwọn ibùṣùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mábù, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.
7 Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí.
8 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.
9 Ayaba Fásítì náà ṣe àṣè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ṣérísésì,
10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Méhúmínì, Bísítà, Hábónà, Bígítà àti Ábágítà, Ṣétarì àti Kákásì, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún un.
11 Kí wọn mú ayaba Fásítì wá ṣíwájúu rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà.
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Fásítì kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidgidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.
13 Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,
14 àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Káríṣénà, Ṣétarì, Ádímátà, Tárísísì, Mérésì, Márísénà àtí Mémúkánì, àwọn ọlọ́lá méje ti Páṣíà àti Médíà tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.
15 Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Fásítì gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ṣérísésì tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”
16 Mémúkánì sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Fásítì ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan Ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba Ṣérísésì.
17 Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obínrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójúu wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ṣérísésì pàṣẹ̀ pé kí á mú ayaba Fásítì wá ṣíwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.
18 Ní ọjọ́ yìí gan-an ni àwọn ọlọ́lá obinrin Páṣíà àti ti Médíánì tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.
19 “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Pásíà àti Médíánì, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Fásítì kí ó má ṣe wá ṣíwájú ọba Ṣérísésì. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó ṣàn jù ú lọ.
20 Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”
21 Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Mémúkánì ṣé sọ.
22 Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbéríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ọ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkálùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé e rẹ̀.