Ẹ́sítà 3 BMY

Ọ̀tẹ̀ Hámánì Láti Pa Àwọn Júù Run

1 Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ṣérísésì dá Hámánì ọmọ Hámádátà, ará a Ágágì lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tó kù lọ.

2 Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hámánì, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Modékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún-un.

3 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Módékáì pé, “È éṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.”

4 Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún-un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hámánì nípa rẹ̀ láti wòó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Módékáì ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun.

5 Nígbà tí Hámánì ríi pé Módékáì kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú.

6 Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Módékáì jẹ́, ó kẹ́gàn àti pa Módékáì nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hámánì ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Módékáì run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ṣérísésì.

7 Ní ọdún kejìlá ọba Ṣérísésì, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù nísánì, wọ́n da Púrì (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hámánì láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Ádárì.

8 Nígbà náà ni Hámánì sọ fún ọba Ṣérísésì pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fánká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tó kù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀.

9 Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàarùn-ún talẹ́ńtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn ṣe iṣẹ́ náà.”

10 Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hámánì ọmọ Hámédátà, ará Ágágì, ọ̀ta àwọn Júù.

11 Ọba sọ fún Hámánì pé, “pa owó náà mọ́” “kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”

12 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀ wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hámánì ti pa láṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ṣérísésì fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.

13 A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́ẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Ádárì kí a sì kó àwọn ohun ìní in wọn.

14 Kí ẹ mú àdàkọ kan ìwé náà kí a tẹ̀ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ó sì di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà.

15 Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ìlé ìsọ́ ti Ṣúsà. Ọba àti Hámánì jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Ṣúsà wà nínú ìdààmú.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10