Ẹ́sítà 2 BMY

Éṣítà Di Ayaba

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ṣérísésì ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Fásítì àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀.

2 Nígbà naà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kòì mọ ọkùnrin rí fún ọba.

3 Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hégáì, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára.

4 Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Fásítì.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

5 Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ọmọ Jáárì, ọmọ Símù, ọmọ Kúsì, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,

6 Ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ́mù, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jéóhákímù ọba Júdà.

7 Módékáì ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hádásà, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní bàbá bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Ẹ́sítà, ó dára ó sì lẹ́wà, Módékáì mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ti kú.

8 Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Ṣúsà, sí abẹ́ ìtọ́jú Hégáì. A sì mú Ẹ́sítà náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hégáì lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.

9 Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojú rere rẹ̀, lẹ́ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ ó pèṣè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún-un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúndíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.

10 Ẹ́sítà kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Módékáì ti pàṣẹ fún-un pé kí ó má ṣe ṣọọ́.

11 Ní ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Ẹ́sítà ṣe wà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.

12 Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ṣérísésì, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjía fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòrùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.

13 Báyìí ni yóò ṣe lọ ṣíwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún-un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba.

14 Ní alẹ́ ni yóò lọ ṣíbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣáásígásì ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyààfi tí inú ọba bá dùn síi, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin.

15 Nígbà tí ó kan Ẹ́sítà (ọmọbìnrin tí Módékáì gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Ábíháílì) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò bèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hégáì, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Ẹ́sítà sì rí ojú rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i.

16 A mú Ésítà lọ síwájú ọba Ṣéríṣésì ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹ́wàá, tí ó jẹ́ oṣù Tébétì, ní ọdún kéje ìjọba rẹ̀.

17 Ésítà sì wu ọba ju àwọn obìnrin tó kù lọ, Ó sì rí ojú rere àti oore ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúndíá tó kù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Fásítì.

18 Ọba sì se àsè ńlá, àsè Ésítà, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbéríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó.

Módékáì Tú Àṣírí Ìṣọ̀tẹ̀

19 Nígbà tí àwọn wúndíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọbà.

20 Ṣùgbọ́n Ẹ́sítà pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́gẹ́gẹ́ bí Módékáì ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tèlé àṣẹ tí Módékáì fún-un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Módékáì.

21 Ní àsìkò tí Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba, Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Sérísésì.

22 Ṣùgbọ́n Módékáì sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Ẹ́sítà, Ẹ́sítà sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Módékáì.

23 Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì já sí òtítọ́, a sì ṣo àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwáju ọba.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10