1 Ọba àti Hámánì sì lọ sí àpèjẹ pẹ̀lú Ẹ́sítà ayaba,
2 Bí wọ́n sì ṣe ń mu wáìnì ní ọjọ́ kejì yìí, ọba sì tún béèrè pé, “Ẹ́sítà ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaà mi, n ó fi fún ọ.”
3 Nígbà náà ni ayaba Ẹ́sítà dáhùn, “Bí èmi bá rí ojú reree rẹ, ìwọ ọba, bí ó bá sì tẹ́ ọláà ńlá à rẹ lọ́rùn, fún mi ní ẹ̀míì mi-èyí ni ẹ̀bẹ̀ mi. Kí o sì pa àwọn ènìyàn mi mọ́-èyí ni ìbéèrè mi.
4 Nítorí a ti ta èmi àti àwọn ènìyàn mi fún àwọn tí yóò pa wá run, à ti ṣe ìdájọ́ wa fún pípa àti píparẹ́. Bí a bá ti lẹ̀ tàwá bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ǹbá dákẹ́, nítorí irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ kò tó èyí tí à ń yọ ọba lẹ́nu sí.”
5 Ọba Ṣéríṣésì sì bi Ésítà ayaba léèrè pé, “ta a ni ẹni náà? Níbo ni ẹni náà wà tí kò bẹ̀rù láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?”
6 Ésítà sọ wí pé, “alátakò àti ọ̀ta náà ni Hámánì aláìníláárí yìí,”Nígbà náà ni Hámánì wárìrì níwájú ọba àti ayaba.
7 Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì, ti ríi dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹ́sítà ayaba nítorí ẹ̀míi rẹ̀.
8 Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngán àsè náà, Hámánì ṣubú sórí àga tí Ẹ́sítà ayaba fẹ̀yìntì.Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?”Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hámánì lójú.
9 Nígbà náà Háríbónà ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n mítà mẹ́talélógún (23 mítà) ni Hámánì ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilée rẹ̀. Ó ṣeé fún Módékáì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.”Ọba wí pé, ẹ ṣo ó rọ̀ sórí i rẹ́!
10 Wọ́n sì ṣo Hámánì sórí igi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọ̀.