4 Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́nàti ìdè ìfẹ́.Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọnMo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bíṢé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bínítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?
6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọnyóò si bá gbogbo irin ẹnú odi ìlú wọn jẹ́yóò sì fòpin sí gbogbo èrò wọn.
7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ miBí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ ọ̀gá-ògo júlọ,kò ní gbé wọn ga rárá.
8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù?Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lìBáwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà?Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù?Ọkàn mi yípadà nínú miÀánú mi sì ru sókè
9 Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹtàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoroNítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyànẸni mímọ́ láàrin yín,Èmi kò ni i wa nínú ìbínú
10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìúnNígbà tó bá búàwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn.