Hósíà 5 BMY

Ìdájọ́ Ń Bọ̀ Lórí Ísírẹ́lì Àti Júdà

1 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!Ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì!Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!Ìdájọ́ yìí kàn yín:Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní MísípàÀwọ̀n ti a nà sìlẹ̀ lórí Tábórì

2 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyànGbogbo wọn ni èmi ó bá wí,

3 Mo mọ ohun gbogbo nípa ÉfúráímùÍsírẹ́lì kò sì pamọ́ fún miÉfúráímù, ní báyìí ó ti di alágbèrèÍsírẹ́lì sì ti díbàjẹ́

4 “Iṣe wọn kò gbà wọ́n láàyèláti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.Ẹ̀mí àgbèrè wà láàrinwọn kò sì mọ Olúwa.

5 Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí lé wọn;Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti Éfúráímù pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Júdà náà sì kọṣẹ̀ pẹ̀lú wọn.

6 Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹranàti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,wọn kò ní rí i,ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn.

7 Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí Olúwawọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè.Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntunwọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn.

8 “Fọn fère ní Gíbíà,kí ẹ sì fun ipè ní Rámà.Ẹ pariwó ogun ní Bẹti-Áfélìmáa wárìrì, ìwọ Bẹ́ńjámínì.

9 Éfúráímù yóò di ahoroní ọjọ́ ìbáwíláàrin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lìMo sọ ohun tí ó dájú.

10 Àwọn olórí Júdà dàbí àwọn tí ímáa yí òkúta ààlà kúrò.Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi léwọn lórí bí ìkún omi.

11 A ni Éfúráímù lára,A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà

12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí ÉfúráímùMo sì dàbí ìdin sí ara Júdà.

13 “Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀,tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ,ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ṣùgbọ́n kò le è wò ó sànbẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná

14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù,bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà.Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mitítí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀biwọn yóò sì wá ojú minínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14