Hósíà 14 BMY

A Mú Ísírẹ́lì Padà Bọ́ Sípò

1 Yípadà ìwọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!

2 Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,Kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.Ẹ sọ fún un pé:“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wákí o sì fi oore ọ̀fẹ́ gbà wá,kí àwa kí ó lè fí ètè wa sán-an fún ọ

3 Asíríà kò le gbà wá là;A kò ní í gorí ẹsin ogunA kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé‘Àwọn ni òrìṣà wasí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọnaláìní baba tí ń rí àánú.’

4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ wọn.

5 Èmi o dàbí ìrì sí Ísírẹ́lìwọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílìyóò sì ta gbòngbòkédárì ti Lébánónì

6 Àsẹ̀sẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,Didan ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi ólífìÒórùn rẹ yóò sì dàbí igi sídà ti Lébánónì.

7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.Yóò rúwé bi ọkà.Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lébánónì.

8 Ìwọ Éfúráímù; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?Èmi ó daba! lóhùn, èmi o sì ṣe ìtọ́jú rẹ.Mo dàbí igi tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

9 Ta ni ọlọgbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyíTa a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.Tí tọ́ ni ọ̀nà Olúwaàwọn olódodo si ń rìn nínú wọnṢùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ nìyóò kọsẹ̀ nínú wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14