Hósíà 4 BMY

Ẹ̀sùn Tí Ọlọ́run Fi Kan Ísírẹ́lì

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùnkan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà

2 Afi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyànolè jíjà àti panṣágà.Wọ́n rú gbogbo òfin,ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

3 “Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogboolùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀runàti ẹja inú omi ló ń kú.

4 “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹ̀nìkéjìnítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbíàwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà

5 Ẹ ń ṣubú lọ́sàn-án àti lóruàwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lúu yínÈmi ó pa ìyá rẹ run

6 Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;nítorí pé ẹ ti kọ òfìn Ọlọ́run yín sílẹ̀Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.

7 Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí ibẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú

8 Wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn miWọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.

9 Yóò wá ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà ríÈmi ó jẹ gbogbo wọn níyà nítorí ọ̀nà wọn.Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

10 “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwasílẹ̀

11 ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù

12 Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igiỌ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn sìnàwọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.

13 Wọ́n ń rúbọ lórí àwọn òkè ńlá,Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeréLábẹ́ igi óákù, àti igi pópúlárìàti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dáraNítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrèàti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.

14 “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yínníyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrètàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrènítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.Wọ́n sì ń rúbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ilé òrìṣà.Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Ísírẹ́lìÌdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Júdà di ẹlẹ́bi.“Ẹ má ṣe lọ sí Gílígálì.Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Bẹti-ÁfénìẸ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láàyè nítòótọ́!’

16 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe agídíbí alágídí ọmọ màlúùBáwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọnbí àgùntàn ní pápá oko tútù?

17 Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!

18 Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tánwọ́n tún tẹ̀ṣíwájú nínú àgbèrèàwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.

19 Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14