Hósíà 12 BMY

1 Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́;Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́.Ó sì ń gbèrú nínú irọ́Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú ÁsíríàÓ si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì.

2 Olúwa ní ẹ̀sùn tí yóò fí kan Júdàyóò fìyà jẹ Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀yóò sì sán fún-un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.

3 Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

4 Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀Ó bá Olúwa ní Bẹ́tẹ́lìÓ sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,

5 àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀

6 Ṣùgbọ́n ìwọ́ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;Di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo múkí ẹ sì dúró de Olúwa yín nígbà gbogbo.

7 Oníṣòwò ń lo òṣùnwọ̀n èkéÓ fẹ́ràn láti rẹ́nijẹ.

8 Éfúráímù gbéraga,“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéétàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́”

9 “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì;èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì

10 Mo sọ fún àwọn wòlíì,mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́nmo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”

11 Gílíádì ha burú bí?Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì?Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebènínú aporo oko.

12 Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù;Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwóó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó.

13 Olúwa lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì,nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

14 Ṣùgbọ́n Éfúráímù ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí orí rẹ̀òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14