2 “Ẹ bá ìyáa yín wí, ẹ bá a wí,nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀àti àìsòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
3 Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòòhòÈmi yóò sì gbé e kalẹ̀ lá ìwọṣọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a bí i.Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀Èmi yóò sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́.
4 Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́
5 Ìyá wọn jẹ́ aláìsòótọ́ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi,tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,aṣọ oríṣìíríṣìí, òróró àti ohun mímu’ lẹ́yìn.
6 Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nàÈmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
7 Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.Nígbà náà ni yóò sọ pé,‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsìnyí lọ.’
8 Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi niàti ẹni tó fún un ní ọkà,ọtí-wáìnì tuntun àti òróróẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Báálì