3 “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
4 Alágbèrè ni gbogbo wọnwọ́n gbóná bí ààrò àkàràtí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìnìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5 Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wawáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbónáó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6 Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààròwọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkísí,ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òruó sì bú jáde bí ọ̀wọ́ iná ní òwúrọ̀.
7 Gbogbo wọn gbóná bí ààròwọ́n pa gbogbo olórí wọn run,gbogbo ọba wọn si ṣubúkò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
8 “Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;Éfúráímù jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9 Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ runṣùgbọ́n kò sì mọ̀,Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiribẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsíi