1 “Ọlọ́run rẹ̀. Fi ìpè sí ẹnu rẹ!Ẹyẹ igún wà lórí ilé Olúwanítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2 Ísírẹ́lì kígbe pè mí‘Áà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́!’
3 Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀
4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ miwọ́n yan ọmọ aládé láì si ìmọ̀ mi nibẹ̀.Wọ́n fi fàdákà àti wúràṣe ère fún ara wọn,kì a ba le ké wọn kúrò.
5 Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nùÌbínú mi ń ru sí wọn:yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?