11 “Nítorí Éfúráímù ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13 Wọ́n ń rúbọ tí wọ́n yàn fún mi,wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọnyóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Wọn yóò padà sí Éjíbítì
14 Nítorí Ísírẹ́lì ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kansí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”