7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́wọ́n sì ká ìjìIgi ọkà kò lórí,kò sì ní mú oúnjẹ wá.Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkààwọn àlejò ni yóò jẹ.
8 A ti gbé Ísírẹ́lì mì,Báyìí, ó sì ti wà láàrin àwọn orílẹ̀ èdèbí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Síríàgẹ́gẹ́ bí ẹhànnà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń rìn kiri.Éfúráímù ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárin orílẹ̀ èdèÈmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsìn yìíWọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànùlọ́wọ́ ìnílára ọba alágbára.
11 “Nítorí Éfúráímù ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13 Wọ́n ń rúbọ tí wọ́n yàn fún mi,wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọnyóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Wọn yóò padà sí Éjíbítì