6 Rún un kí o sì da òróró síi lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni.
7 Bí ó bá jẹ́ inú páànù ni o ti se ọrẹ ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára àti òróró.
8 Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ,
9 Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
10 Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
11 “ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa.
12 Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn.