10 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.
11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù bàbá rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
12 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
13 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n í ti bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
14 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyatọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má baà gbilẹ̀ láàrin yín.
15 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà.
16 “ ‘Bí obìnrin kan bá sún mọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn