30 Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.
31 “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.
32 Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.
33 Tí ó sì mú yín jáde láti Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”