16 “ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n sètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n ómà èso bárílì.
17 Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó yà ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọ tẹ́lẹ̀ náà ni kí o san.
18 Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù.
19 Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdá márùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀.
20 Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tàá fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́.
21 Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.
22 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa.