14 Ó sì mú akọ mààlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà.
15 Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.
16 Mósè tún mú gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú, èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.
17 Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú àwọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.
18 Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.
19 Mósè sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.
20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.