10 “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrin yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ ọ yín.
11 Orúkọ mi yóò tóbi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀ oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ ọ̀ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.
12 “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ́ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn.
13 Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.“Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó farapa, arọ àti olókùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rúbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí.
14 “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹ̀ran tó lábùkù rúbọ sí Olúwa; nítorí Ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.