1 Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi!Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà.Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹIrun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì.
2 Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbòtí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn.
3 Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;Ẹnu rẹ̀ dùn.Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètìlábẹ́ ìbòjú rẹ
4 Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì,tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́,gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
5 Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjìtí wọ́n jẹ́ ìbejìtí ń jẹ láàrin ìtànná lílì.
6 Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀tí òjìji yóò fi fò lọ,Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíáàti sí òkè kékeré tùràrí.