5 Àwọn baba yín, níbo ni wọ́n wà? Àti àwọn wòlíì, wọn ha wà títí ayé?
6 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pà ni àṣẹ fún àwọn ìrànsẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín?“Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”
7 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sébátì, ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Sekaráyà, ọmọ Berekáyà ọmọ Idò wòlíì wá, pé,
8 Mo rí ìran kan ni òru, si wò ó, ọkùnrin kan ń gun ẹṣin púpa kan, òun sì dúró láàrin àwọn igi míritílì tí ó wà ní ibi òòji; lẹ́yìn rẹ̀ si ni ẹ̀ṣin púpa, adíkálà, àti funfun gbé wà.
9 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí Olúwa mi?”Ańgẹ́lì tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”
10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrin àwọn igi míritílì sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”
11 Wọ́n si dá ańgẹ́lì Olúwa tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”