9 Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí Olúwa mi?”Ańgẹ́lì tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”
10 Ọkùnrin tí ó dúró láàrin àwọn igi míritílì sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”
11 Wọ́n si dá ańgẹ́lì Olúwa tí ó dúró láàrin àwọn igi mirtílì náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti ríi pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”
12 Nígbà náà ni ańgẹ́lì Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jérúsálẹ́mù, àti fún àwọn ìlú ńlá Júdà, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”
13 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.
14 Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbé wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì.
15 Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’