Sekaráyà 3:4-10 BMY

4 Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”Ó sì wí fún Jóṣúà pé, “Wòó, mo mú kí àìṣedéédé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”

5 Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn si fi gèlè mímọ́ wé e lorí, wọn si fi aṣọ wọ̀ ọ́. Ańgẹ́lì Olúwa sì dúró tì í.

6 Ańgẹ́lì Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Jóṣúà pé:

7 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní àyè láti rìn láàrin àwọn tí ó dúró yìí.

8 “ ‘Gbọ́, ìwọ Jóṣúà olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jòkòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsí i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi, Ẹ̀ka, wá.

9 Nítorí kíyèsí i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Jóṣúà; lórí òkúta kán ni ojú méje wà: kíyèsí i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.

10 “ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”