12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrin yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín:
13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábàápín ìyà Kírísítì, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.
14 Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín (ní ọ̀dọ̀ tí wọn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi, ṣùgbọ́n ní ọ̀dọ̀ ti yín a yìn ín lógo.)
15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí àpànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣé búburú, tàbí bí ẹni tí ń tọjúbọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.
16 Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí kírísítẹ́nì kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.
17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀hìn àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọ́run yó ha ti rí?
18 “Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́sẹ̀ yóò gbe yọjú sí?”