9 Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.
10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrin ara yín, bí ìríjú rere tí oníruúrú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí í ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fifún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. (Àmín).
12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrin yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín:
13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábàápín ìyà Kírísítì, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.
14 Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín (ní ọ̀dọ̀ tí wọn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi, ṣùgbọ́n ní ọ̀dọ̀ ti yín a yìn ín lógo.)
15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí àpànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣé búburú, tàbí bí ẹni tí ń tọjúbọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.