8 Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìn rere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a já sí ólóòótọ́,
9 bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a si wà láàyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,
10 bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí talákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
11 Ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa payá sí yín.
12 A kò ni yín lára nítorí wa, ṣùgbọ́n a ni yín lára nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀yin fúnra yín.
13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, (èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé) ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín payá pẹ̀lú.
14 Ẹ má ṣe fí àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí idápọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdápọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?