5 Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ̀ bí ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti ìfipágbà.
6 Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kínún, kínún ni yóò ká; ẹní tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká.
7 Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọ̀kàn rẹ̀; kì í ṣe àfìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọ́dọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ.
8 Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo.
9 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:“Ó tí fọ́nká; ó ti fifún àwọn talákà;Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
10 Ǹjẹ́ ẹni tí ń fí irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i.
11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.